‘B’iṣẹ ò bá pẹ’ni, ẹnìkan kìí pẹ’ṣẹ’ ni mínísítà ètò iná mọnamọna lorileede yìí, Adebayo Adelabu fi ọrọ na ṣe, latari imurasilẹ fún eto ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ t’odun 2027. Kíákíá ni Adelabu ti bere ètò lati fi Gómìnà ìpínlẹ̀ na leyin ti odun mejo Seyi Makinde ba ti pe.
Ìdí nì wípé, àwọn ẹgbẹ kan tó n ṣe agbateru bi Adelabu yóò ṣe de ipo Gómìnà, iyen “Mandate Group Bayo 4 Gomina” ti bẹrẹ ìpàdé ni pereu, ti won si tun ti kede wípé àwọn yóò ṣe ìpàdé míràn lójó Tusidee ọṣẹ yìí lati le tèsíwájú lori imusẹ èròngbà wọn.
Nínú atejade kan ti won tẹ sórí ìkànnì WhatsApp ẹgbẹ ohun, ni won ti kede ipade na.
Won ni: “Eyi ni lati fi to gbogbo àwa ọmọ ẹgbẹ onitesiwaju ti a gbàgbó nínú èròngbà egbe yii (Bayo 4 Gomina) wipe, ipade pàtàkì yoo waye lojo Tosidee, December 17, 2024, ni Political Chamber, tó wà l’adugbo Obasa, n’Ibadan, ni déédé agogo mẹrin osan,”.
Adelabu tó jẹ oyè mínísítà fún ètò mọnamọna labẹ ààrẹ Bola Tinubu, ti f’igba kan gbe apoti ibo fun Gómìnà labe ẹgbẹ oselu Accord n’ipinle Oyo sùgbón tó fìdí rẹmi nínú ìdìbò na.