Àjọ tó n gbógun ti ìwà ọ̀daràn ọrọ-aje àti ṣiṣe-owo-kumo-kumo, ìyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti fi ọwọ sìnkún òfin mú obìrin kan (Fatima Muhammed), ti wọn ni o n fi owó náírà run imú nílùú Maiduguri nile Hausa. Gẹgẹ bi atẹjade àjọ EFCC ṣe ti ṣàlàyé, ọjọ tusidee ọsẹ yìí ni wọn mú obìrin na s’atimole. Ẹsun ṣiṣe owó náírà kumokumo ni won fi kan an.
EFCC ní, inú fídíò kan lórí ikanni Tiktok ni wọn ti ri Fatima to n fi owo naira (N500) ko ìdòtí (ikun imu) jáde lati imu rẹ lọna to tabuku sí owó ilẹ Nàìjíríà.
Lọ́gán ti àwọn agbofinro ri fídíò ohun, ni won gùn lé itopinpin lati mú obìrin ohun. Lẹnu iwadi wọn ni won ti rí àrídájú wípé olu-ilu ipinlẹ Borno, ìyẹn Maiduguri ni Fatima fi ṣe ibùgbé. Lójú ẹsẹ ni wọn si gbe obirin na lo si atimole EFCC to wa ni àgbègbè ohun, fun ìtèsíwájú ìwádìí.
EFCC ni, kété ti àwọn ba pari ìwádìí, awon yoo gbe obirin na lo si ile ẹjọ lati lo ṣalaye nkan to ri lọbẹ, to fi gaaro ọwọ.
Titabuku owo naira jẹ iwa ọ̀daràn kan ti ofin Nàìjíríà o faramo rárá. Ṣebi eo gbagbe wípé, esun yii kànnà lo gbé ọmọkunrin kan to n múra bi obìrin, ìyẹn Bobrisky dé ogba ẹwọn níbi to ti lo oṣù mẹfa gbáko ní nkan bi ọdún diẹ sẹyin. Nina owó naira lójú agbo ìnáwó lọna to lodi s’ofin lo sọ Bobrisky d’ero ogba-ewon







