Ajijangbara fun idasile orileede Yoruba (Yoruba Nation), Oloye Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan tun mo si Sunday Igboho ni oun ti setan lati tu asiri awon oloselu to lowo si jiji ti won ji awon akeko ati oluko won gbe lagbegbe ijoba ibile Oriire, nipinle Oyo l’osu to koja yii.
Sebi eo gbagbe wipe lojo keedogun osu karun odun yii lawon agbebon ya wo awon abule kan bii Yawota ti won si fi tipatikuuku ko awon oluko ati akeko to le ni ogoji lapapo, ti won si ko won salo sinu igbo. Koda, won be okan ninu awon oluko na l’Ori ti won si fi fidio ibenilori na lede. Ileewe meta ti won ti ji awon omo na ko ni: Baptist Nursery and Primary School, Yawota; Community Grammar School, Esiele; ati L.A. Primary School.
Latigba na ni, awon agbofinro ti n gbiyanju lati ri awon omo na gba pada. Koda, egbe awon oluko nipinle na ati awon ipinle miran kaakiri ile Yoruba ti gun le iyanselodi ati wiode, ti won si ti gbogbo ileewa pa, titi ti di igba tawon omo na yoo fi di riri.
Sugbon lasiko to n ba awon olori egbe akeko (National Association of Nigerian Students) labe akoso aare won tuntun, Akinteye Bàbàtunde soro lojo Wesidee niluu Ibadan, Oloye Adeyemo fi esun kan awon oloselu kan ti ko daruko won, wipe awon gan-an lo wa nidi oro na.
O ni oun ti setan lati ko awon omo-ogun oun sodi, lati mori le inu igbo ti awon agbesumomi na sapamo si, sugbon ijoba ipinle Oyo o gba oun laaye lati se bee. O fi kun oro re wipe oun o beere owo kankan lowo ijoba gomina Seyi Makinde lati le gun le ise na. O ni ase ati atyileyin lasan loun nilo.
E gbo oro die lati enu Sunday Igboho: “Ti won ba gba mi laaye, ti mo wole to awon ajinigbe yen lo, awon gan-an papa a salo patapata. Won kii se iwin, bee won kii se nkan ti eeyan o le fi oju ri. Eeyan lawon na, fun idi eyi, agbara wa le ka won.
“Emi mo awon oloselu to wa nidi oro ajinigbe yii, bi won o ba si jawo ninu iwa buruku yii, ma a da oruko won fun araye gbo. Emi mo won dada. Awon oloselu yen lo n fun awon agbesumomi yii ni ibon ti won nlo lati fi se ise ibi yii.
“Iru iwa bayii ti won hu si Aare ana, Goodluck Jonathan, na ni won tun hu si Aare Bola Tinubu lowolowo yii. Won fe da oju gbogbo nkan ru mo ijoba lowo ni. Koda, won a tun ma a gbe iroyin ofegee kiri lati le mu ki awon eeyan ma tele Tinubu mo. Mo ti fa ara mi kale lati lo koju awon ajinigbe yii, sugbon ijoba ipinle Oyo ni rara, ko si aaye fun mi.
“Leyin igba na ni won tun so fun mi, wipe awon ajinigbe ohun ni, ti mo ba fi le wo’nu igbo wa baa awon, awon yoo pa gbogbo awon omo ileewe na to wa lakata won patapata. To ba je looto nijoba fe gba awon omo wonyi pada, ki won fun emi ati awon omo mi laaye lati lo ba awon ajinigbe yii, kiakia ni won ma kuro ni ile Yoruba” Sunday Igboho lo n soro bee







