Oba ran nise, odo-oba kun. Ise oba o se maa je, bee na ni Odo-oba o se binu wo. Owe yii gan-an lo n se apejuwe ipo ti gbajugbaja oloselu, Sineto Sarafadeen Alli yoo wa lowo bayii. Nkan meji otooto lo se e se ko ma a da okan baba na ru bayii, – akoko, igbiyanju re lati dijedupo gomina ipinle Oyo leyin isejoba Injinia Seyi Makinde. Ekeji, ni ti iwuye gegebi oloye-agba, iyen Oba labe Olubadan, ti ijoba sese kede re.
Idi ni wipe, ti Sineto Alli ba pinu lati de ade gegebi Oba labe Olubadan, a je wipe ko se e se fun un mo, lati tun dijedupo gomina tabi lati kopa ninu eto oselu mo. A je wipe, enikan kii je meji laba Alade loro ohun je fun agba oloselu ohun.
Bo tile je wipe, alagba Sarafadeen Alli o tii kede ni pato wipe oun fe dijedupo gegebi gomina ipinle Oyo, ahuyehuye ti n lo nigboro to ojo meta kan wipe, ipo gomina ohun lo wa lokan baba na. koda, lose to koja yii, ni iroyin kan lale hu, wipe awon agba egbe oselu All Progressives Congress (APC) ni Guusu-Iwo-Orun (Southwest) ti fenu ko wipe kawon o gbe tikeeti idijedupo gomina Oyo le Sarafadeen Alli lowo.
Awon oloselu kan si ti se afomo oro wipe, oro o ri bee rara. Won ni iroyin ofegee lasan ni wipe egbe oselu APC ti fenuko lori omo-oye fun ipo gomina.
Sugbon, agbara-kaka ni iroyin ohun fi bale, ti ikede ijoba ipinle oyo na fi tele e, -ile-ise ijoba to n moju to eto ijoba ibile ati oro oye jije nipinle na (Ministry of Local Government and Chieftaincy Affairs) fi oro lede wipe ojo keta, osu kerin odun yii, lawon yoo de ade fawon Oba tuntun labe Olubadan. Awon ti oye na kan ni, Oloye-agba Akeem Bolaji Adewoyin; Oloye-agba Sarafadeen Abiodun Alli, ati Oloye-agba Kola Babalola.
Ikorita-meta yii gan-an ni alagba Sarafadeen Alli nilo lati se ipinu laarin tikeeti APC fun idijedupo gomina tabi ko gba lati de ade gegebi Oba niluu Ibadan. Koda, asiko to nilo lati se ipinu ohun o ju nkan bi ose kan lo mo.
Gege bi ofin ati isedale Yoruba, gele ti eeyan ba ti je Oba alade, oluwa re o tun lanfaani mo lati tun kopa ninu oselu sise.
Awon kan tile n gbe e pooyi enu wipe, ijoba ipinle Oyo moomo gbe igbese ohun ni, sugbon, ko si aridaju wipe be e loro ri, nitori wipe, atunse ofin oye jije nipinle oyo ti waye lati osu karun-un odun 2023.
Wayi o, ibeere ti awon eeyan n bere ni wipe, se ti Sineto Sarafadeen Alli ba gba lati de ade Oba, nje yoo fi ipo re sile ni ile-igbimo asofin apapo to wa lowolowo, nigba to je wipe ofin o faaye gba Oba Alade lati se oselu.
Kini eyin ro wipe o ye ki baba na o se, nibi ti oro de duro bayii?







