Ìgbàtí, ìgbámú tí kẹrikẹri nba r’òde lọrọ Portable padà já sí lalẹ Furaide, nígbàtí aderinposonu ori Social Media, Carter Efe fi ẹsẹ bamba gba beliiti lọwọ olorin igbalode nni, ti gbogbo ayé tun mọ si “Ìdààmú-Àdúgbò, Wèrè-Olorin”
Ìjà ohùn, to wáyé nínú ọgbà Balmora to wà ni Federal Palace Hotel, Victoria Island, ló jẹ àkànṣe ìjà faaji laarin awọn gbajumọ mejeeji.
Bo tilẹ je wípé, Portable le furukoko ṣáájú ija ohun, agbara rẹ kò ka Carter Efe, débi wípé gbogbo akitiyan rẹ lati f’iya jẹ Efe lo ja si pabo.
Ìpele kẹta (3rd round) ni eleeru ni sun’ko fún Portable, nígbà ti awọn adájọ gbe oriyin fun Carter Efe wipe oun lo bori ìjà ohun pelu ami ayo: 27-30.
K’íjà ohun tó parí, emeewaa ni Portable n so Ẹsẹ di Gídígbò, to n lọ mọ Efe bi iyawo osingin to ṣẹṣẹ wọlé ọkọ.

Ṣáájú ìjà ọjọ Furaide, awon ìlúmọọkà meta otooto ni Portable ti ba ja to si bori won, – Charles Okocha, Speed Darlington ati Atobiloye Kelvin, to ti figba kan jẹ oludaabobo gbajugbaja olorin, Kizz Daniel.
Lásìkò tí o n mura ìjà pẹlú Carter Efe, Portable ni, ko ni gba oun lakoko rara lati lu Efe, nítorí wipe ko to nkankan loju oun. O ni: “Ma kan fi e gba beliiti kẹta. Charles Okocha ati Speed Darlington ti won tiẹ jù e lọ ni gbogbo ona, nina ni ni mo lu wọn papọ. Ambosibosi iwọ kékeré yii” Portable lo n fọ’nu bee.

Sugbon, Efe na daa lohun. O ni, nibi ti ko si ile, ni a ti n jiyan ija. O ni ese kan pere ni Portable yoo gba, ti yoo fi fìdí lulè.
Bo tile je wipe Portable pada gba ju ẹsẹ kan lo, lojo Furaide, Carter Efe lo gbe beliiti rele.








