Aare Onakankanfo ile Yorubs lapapo, Iba Ige Gani Adams ti wo ajijangbara fun ominira orile ede Yoruba, Oloye Sunday Igboho lo si ile ejo giga tipinle Oyo to wa n’Ibadan lori wipe Igboho se akasile ohun re [Adams] lori foonu lasiko ti awon jo n soro. Ati wipe o se alabapin ohun na pelu elomiran lalai so fun oun.
Sugbon Sunday Igboho ni, oun o tii ri iwe ipejo kankan gba lati ile ejo kankan. Lasiko to n gba enu agbejero re, Junaid Sanusi, soro, Sunday Igboho ni oun o mo nipa ejo kankan yato si ejo ti oun pe Gani Adams lori ibanilorukoje, ti o si wa niwaju ile ejo titi di lowolowo yii.
Ninu ejo ti Gani Adams pe Igboho, o ro ile ejo wipe ki won fi ofin de Sunday Igboho, nitori wipe igbese pinpin ohun oun pelu elomiran laiso fun oun, ti se akoba fun oruko oun lopolopo gegebi Aareonakankanfo ti ile Yoruba. Koda, o beere fun owo itanran oni-bilionu marun (N5bn).
O ni gege bi akosile to wa ninu iwe ofin, o lodi patapata wipe ki enikan o fi ohun elomiran ranse si elomiran lali gba ase lowo eni to ni ohun na.
Wayi o, agbejoro Sunday Igboho ni ko si nkankan tawon le so lori oro na titi di igba ti awon yoo fi ri iwe ipejo ti Gani Adams pe, gba. O ni Oloye Igboho o setan lati ba Aareonakankanfo takuroso lori oju ewe iwe iroyin lasan lai se wipe, awon ri iwe ipejo na gba.