Ile Ejo Ijoba Apapo to fi ilu Akure, nipinle Ondo se ibujoko ti fi owo ro ejo kan s’akitan to n pe fun yiyo oruko gomina ipinle na to tun je adijedupo fun egbe oselu All Progressives Congress (APC) kuro ninu eto idibo gomina to koja, Lucky Aiyedatiwa ati Igbakeji re, Olaiyide Adelami.
Adajo to gbo ejo ohun, Bolaji Adegoke so wipe ejo na ko l’ese nile rara. Fun idi eyi, o ni olupejo kan fi akoko ile ejo sofo lasan ni.
Adijedupo to s’oju egbe oselu People’s Democratic Party (PDP) ati egbe oselu ohun paapaa ni won jumo pe Adelami l’ejo wipe kudiekudie to po wa ninu oruko awon iwe-eri ti Adelami ko sile fun ajo alakoso idibo, INEC saaju eto idibo na.
Sugbon Ile ejo ni, ejo ohun ko lese nile rara, nitori pe, won kunna lati gbe ejo ohun lo siwaju ile ejo laarin ojo merinla ti ofin eto-idibo orile ede Naijiria so. Adajo tun ni, ejo ohun ko si ni ibamu pelu iru ejo ti ile ejo le gbo.
Adajo Adegoke ni, olupejoi kunna lati fi idi esun mule daada wipe Adelami yi iwe eri re. Fun idi eyi, o ni ejo na ko l’ese nile rara