Inu ẹkùn, ipahinkeke ati jinnijinni l’awon aráàlú wa titi di bi e ti ṣe n ka iroyin yii, léyìn ti awon agbesunmomi ta n pe ni bandits kọlu àwọn èèyàn kan nínú oko adìyẹ kan tó wà ni Igushi, ni Ìjọba Ibile Ariwa Akure nipinlẹ Ondo.
Ọjọ Tọsidee l’awọn agbébọn bíi márùn ya wọ inu oko ohun, ti won si yinbon pa obìrin kan t’awọn èèyàn l’oun lo ni oko na, àti ọmọ rẹ obirin kan, lásìkò tí wọn n gbìyànjú lati ji awon èèyàn gbé níbẹ̀.
Loju ẹsẹ ni awon méjèèjì si gbe emi mi, ti wọn dagbere f’aye.
Koda, alukooro ile-iṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh na fìdí ọrọ na múlẹ. O ni, bo tilẹ je wípé awon olópàá ri awon eeyan kan gba pada lowo awon ọdaràn na, iya ati omo re ti won yinbo lu, terigbaso.
O wa fi kun ọrọ re wipe, ìwádìí n tẹ síwájú lati ri awon agbébọn na mú.
E gbọ ọrọ lenu Jimoh: “Ileese ọlọpaa ìpínlẹ̀ Òndó bu ẹnu atẹ lu iwa aburú t’awon kan hu ati ìjàmbá to sele lagbegbe Igushi, leyi ti a ti pàdánù èèyàn meji.
“Ile-iṣẹ olópàá n mu da awon eniyan loju wipe, a ti se eto, a si ti gbe igbese lati rii daju wipe eto aabo emi ati dukia o mehe nipinle Òndó”
Alukoro ọlọ́pàá na wa rọ awon aráàlú wipe ki won wa lojufo, ati wipe ki won si fowosowopo pelu awon olópàá lati rii wipe ọwọ sìnkún òfin tẹ awon ọdaràn na laipẹ.







