Egbe oselu All Progressives Congress (APC) tipinle Osun ti jawe fun minisita abele labe ijoba Muhammadu Buhari, iyen Ogbeni Rauf Aregbesola, wipe ko lo joko jee fun igba die gege bi omo egbe. Won ni baba na ti n t’ase agere tipe, o ti n huwa lodi si egbe oselu APC. Koda, egbe tun se igbekale iko olubawi ti yoo se iwadi awon esun ti won fi kan Aregbesola lojuna a ti fi iya to to jee gege bi alaale egbe.
Lara esun na ni wipe, gomina ana nipinle Osun n ledi apopo pelu awon egbe oselu alatako nipinle na lati yi egbe APC lagbo da sina. Won ni, egbe kan ti Aregbesola ko jo, iyen ‘Omoluabi Caucus’ ni Oloselu na n lo lati fi se atako fun egbe APC. Alaga egbe nipinle na, alagba Tajudeen Lawal ati akowe egbe Kamar Olabisi ni won jumo bu owo lu iwe ti won fi ja’we jokojee le Rauf Aregbesola lowo lojo Tusidee ose to koja yii.
Awon esun miran gegebi iwe ti egbe APC fi lede ni wipe Aregbesola n soro nita gbangba lati tako awon agba egbe bii Aare Bola Tinubu, Alaga egbe teleri, Oloye Bisi Akande ati gomina teleri nipinle Osun, Gboyega Oyetola. WOn ni Aregbesola tun ko jale lati kopa tabi se iranwo fun awon eto APC lorisirisi nipinle na. Koda, won ni minisita ana to ti figba kan je korikosun fun aare Tinubu ko lati dibo fun egbe oselu na lati odun 2019 titi d’oni.
Atejade egbe salaye wipe awon oloye egbe lati woodu Aregbesola ni Ijoba ibile Ilesa East lo kowe si egbe wipe ki won o gbe igbese lati yo Aregbesola kuro ninu egbe fun’gba die na.
Die ree ninu atejade egbe APC nipinle Osun “Latari iwe esun ti awon oloye egbe nijoba ibile Ilaoorun Ilesa fi ranse, awa olye egbe ipinle fi asiko yii yo Rauf Aregbesola kuro ninu egbe fun’gba die na, gegebi alaale iwe ofin wa, ori kokanlelogun (Article 21(3)(vi)(c)). A yo Aregbesola kuro ninu egbe titi di igba ti ao fi pari iwadi wa
“Fun idi eyi, egbe ti se agbekale igbimo oniwadi, ti yoo to pinpin awon esun na, ti yoo si fi esi re ranse si awon alase egbe laarin ojo merinla si asiko ti a wa yi. Igbimo ohun yoo si kowe si Aregbesola lati wa so t’enu re lori awon esun na”
Lati igba ti egbe APC ti yan Gboyega Oyetola, to je ibatan Tinubu gegebi adijedupo gomina ipinle na ni gbonmisii-omiotoo ti n waye laarin Aregbesola ati Tinubu ati awon igun kan ninu egbe oselu APC nipinle na.