Abenugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọnarébù Adebo Ogundoyin ti kede ìpinu rẹ lati dijedupo Gómìnà ìpínlè na lọdun 2027.
Ọsan Sande ni aṣòfin ohùn fi ọrọ na lede lẹyin ìpàdé to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) jakejado agbègbè ìbàràpá.
Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, Ogundoyin ni àwọn aráàlú káàkiri ilẹ̀ ìbàràpá ni wọn fi ẹnu ko, wipe k’oun o jade lati gbe àpótí ìdìbò.
E gbọ diẹ nínú ọrọ rẹ: “Ni ìdáhùn si ìpè àwọn èèyàn ní mo ṣe n kede wipe, emi na ti ṣetan lati dijedupo Gómìnà ìpínlè Ọ̀yọ́. Eléyìí kìí ṣe ìpinu adanikanse. O jẹ ojuṣe tó wáyé latari ipe àwọn èèyàn fún ìṣèjọba ajumọṣe ti yóò mú àbájáde rere dani”.
Ogundoyin wa dupẹ lọwọ ifokantan àwọn aráàlú ninu rẹ.
O fi kún ọrọ rẹ wípé, bákannáà l’oun tun ṣe ipade pẹlu awọn leekan-leekan nílùú Èrúwà, to si je wipe bákannáà lọmọ s’orí, tí awon na si n so wipe gboin-gboin lawọn wà leyin rẹ.
Ọdún 2019 ni wọn yan Adebo Edward Ogundoyin sipo gẹgẹ bi abenugan ile ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlè Òyó. Ẹkùn ìdìbò ila-oorun ìbàràpá ni o n sojú fun nílé ìgbìmọ̀ na.
Oṣu keji ọdun 1987 ni a bi aṣòfin Ogundoyin gẹgẹ ọkan nínú àwọn ọmọ ìlúmọọkà onisowo nni, Adeseun Ogundoyin. O kàwé ni fasiti Babcock to wa nílùú Ilisan Remo, nipinlẹ Ogun.







