Igbakeji aare teleri, Atiku Abubakar ti kowe kuro ninu egbe oselu Peoples Democratic Party (PDP). Osan Weside yii lo fi iwe na ranse si alaga egbe oselu PDP to wa ni woodu re to wa ni Jada 1 ward, ni ijoba ibile Jada, Ipinle Adamawa.
Kikowe fi egbe na sile ko seyin didarapo ti Atiku dara po egbe oselu African Democratic Congress (ADC) to je egbe ti awon oloselu alajosepo, iyen coalition fe lo lodun 2027 lati dijedupo ninu eto idibo odun na.
Abdul Rasheeth to je amugbalegbe pataki fun igbakeji aare na, lo fi leta ti Atiku fi fi egbe PDP lede lori ikanni ibanidore X, leyi to tako oro ti amugbalegbe Atiku lori eto iroyin, Paul Ibe ti koko so wipe Atiku ko ni fi egbe oselu PDP rara, latari bi awon kan se n gbe e pooyi enu wipe Atiku fe kuro ninu egbe na. Ibe ni aheso oselu lasan loro ohun.
Sugbon, iwe ti Rasheeth fi sori Intaneeti je ka mo wipe, Atiku ti ko eru re kuro ninu egbe oselu PDP. E gbo nkan ti igbakeji aare ana, to tun je adijedupo aare lopolopo igba, ko sinu iwe na:
“Mo n ko iwe yii lati dekun jije omo egbe People’s Democratic Party (PDP) ni kia. Mo n lo akoko yii lati dupe gidigidi fun awon anfaani ti egbe na ti fun mi lateyin wa.
“Jije igbakeji aare fun saa meji gbako ati jije omo-oye adijedupo aare lemeeji otooto kii se nkan kekere rara ninu irin-ajo aye mi.
“Gegebi okan ninu awon to da egbe PDP sile, o je nkan to ba mi lokan je gidigidi wipe mo le gbe iru igbese yii” Atiku lo koo sinu iwe to ko si alaga PDP ni Woodu re, l’Adamawa. O fi kun oro re pe, ipa ti PDP n gba laipe yii, yato gedengbe si ipa ti awon la sile fun egbe na latibere. Fun idi eyi, oun o le te siwaju mo lati ma a je omo egbe PDP.







