Gboogi ninu egbe oselu New Nigeria People’s Party (NNPP) to tun ti figba kan je gomina ipinle Kano ri, Rabiu Musa Kwankwaso ti kowe fipo re sile gegebi omo egbe NNPP. Osan Sonde oni lo fi iwe re sowo si awon alakoso egbe ohun.
Ninu leta to ko, Kwankwaso ni “gegebi ojulowo omo-egbe, ipinu yii o rorun fun mi lati se, sugbon latari bi nkan se n lo lagbo oselu orile ede yii, leyi to nilo ajumose pelu awon elomiran lona to mu ogbon-atinuda dani, mo se ipinu lati darapo mo egbe miran ninu eyi ti anfaani po fun mi lati le kopa rere ninu ayipada to dara fun orile ede Naijiria.”
Bi eo ba gbagbe, Kwankwaso lo gbe apoti idibo gegebi adijedupo aare ninu egbe oselu NNPP lodun 2023. O dupe lowo awon agbaagba egbe ohun fun atileyin ti won se fun oun, paapajulo alaga gbogboogbo, Ajuji Ahmed ati awon leekan-leekan miran.
Bee na lo tun dupe pupo lowo awon alatileyin re, ninu egbe Kwankwasiyya Movement jakejado ipinle Kano, Ile Hausa ati Orile-ede naijiria nile-loko.
O wa se afikun oro re, o ni: “Ao te siwaju lati ni ajosepo to loorin pelu awon miran lojuna ati mu igba otun ati ojo-ola to dara ba orile ede naijiria”
Bo tile je wipe, Kwankwaso o so ni pato, egbe oselu to fe daramo, ahuyehuye kan ti n lo nigboro saaju asiko yii wipe, egbe oselu African Democratic Congress (ADC) lo se e se ki o darapo mo laarin ose yii.







