Pẹlu bi nkan se dúró l’agbo òṣèlú Nàìjíríà lọwọlọwọ, o ṣe e ṣe ki adijedupo Gómìnà ipinlẹ Eko, nínú ẹgbẹ òṣèlú Labour Party, lọdun 2023, Gbadebo Rhodes-Vivour o darapọ mọ ẹgbẹ òṣèlú ajumọṣe (coalition) African Democratic Congress (ADC) laipe, ko si se be dije dupo gomina nínú ẹgbẹ na lọdun 2027.
Àpẹẹrẹ èyí farahàn lojo Tusidee léyìn ti Akòwé fidihe l’egbe ADC to tun ti figba kan jẹ Gómìnà ipinle Osun, Rauf Aregbesola ṣe pàdé idakonko pelu Rhodes-Vivour l’Ekoo.
Lẹyìn ìpàdé yii ni ọkùnrin na bọ sori ikanni ibanidore X, lati kede ìpàdé ohun pelu Aregbesola.
E gbọ nkan to ko lede: “Mo ṣe ipade nla kan pelu ọgbẹni Rauf Aregbesola lonii.
“Ko si ani-ani kankan ninu erongba wa, bee na si ni, ko si Ifaseyin kankan rara nínú ìpinnu wa. Isọdọtun Nàìjíríà ati Ipinle Eko fun tonile-talejo, ti dandan fun wa lati mu waye” Rhodes-Vivour lo so bẹẹ
Laipe yii ni owuye kan lati inu egbe òṣèlú LP to tun je okan lara awon omoleyin Rhodes-Vivour s’enu foro sọ fún iwe iroyin TheWest wipe, ko ni pe mọ ti okunrin ohun yóò fi kọwe kuro ninu egbe Labour lati darapọ mo ẹgbẹ ADC. Koda o fi yẹ akoroyin wa wipe, Aregbesola fi da Rhodes-Vivour loju ninu ipade ohun wipe oun yoo se atilẹyin fun lati ri tikeeti idejedupo gomina gba ninu ẹgbẹ ADC fun eto idibo 2027.







