Agbarijopo àwọn ọmọ ìpínlè Ògùn kan ti wọn n pe ara wọn ni “EgbaLokan Agenda 2027” ti ṣe afọmọ ọrọ kàn to n jà rànyìn-rànyìn kálẹ wípé wọn ti bu ọwọ lu Sineto Adeola Olamilekan Yayi gẹgẹbi eni tàwọn yóò ti lẹyìn láti di gomina ìpínlẹ̀ na lọdun 2027. Egbé EgbaLokan Agenda 2027 ni irọ pombele lọrọ ohun àti wípé awon o tii bu ọwọ lu ẹnikẹni ti awon yóò ṣe atilẹyin fún, láti de ipò Gómìnà.
Alága ẹgbẹ́ ohun, Mustapha Abdulhakeem, nínú atẹjade kan to fi lede s’alaye wípé, bi àwọn ba tiè fẹ fi ontẹ lu ẹnikẹni, irú eni bẹẹ yóò jẹ ọmọbibi iran Ègbá.
Ṣèbí eo gbàgbé wípé ọmọbibi iran Yewa ni Yayi jẹ ti o sìn sójú ẹkun idibo Ìwọòrùn Ogun nílé ìgbìmò asofin àgbà. Leyin to ṣe Asojusofin ati Seneto n’ipinle Eko lo pada si ìpínlè Ogun lati lo dijedupo Seneto, to si se bee ja ewe Olubori. Latigbana na ni ẹnu si ti n kun un wípé o fe gbé àpótí lati di Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun.
Abdulhakeem fi kun ọrọ rẹ wipe egbe EgbaLokan Agenda 2027 koi tii yan ẹnikẹni, yala ọmọbibi ègbá tabi ẹlòmíràn gẹgẹbi àyànfẹ ẹgbẹ ohun.
Iṣẹ kìí déédé ṣẹ, lo fa atejade ti Abdulhakeem ko ranse s’àwon oniroyin.
Laipe yii ni ìròyìn kan tankale wipe okan gboogi ninu awon ọmọ ẹgbẹ na, Purofeso Yemi Oke fi owo si Yayi lati di Gómìnà ipinle na leyin Dapo Abiodun to wa lori aleefa lọwọlọwọ sugbon ẹgbẹ EgbaLokan Agenda 2027 so wipe, Purofeso Oke kii se agbẹnusọ ẹgbẹ na. Fun idi eyi, ọrọ tirẹ lásán lo sọ.
E gbọ oro alaga: “O ṣe ni laanu wípé orúkọ EgbaLokan Agenda 2027 yo jade ninu awuyewuye to n lo lowo wipe a ti fi ontẹ lu Seneto Yayi gẹgẹbi eni ti yóò dupe gomina lodun 2027.
“Ọrọ na, ti awon kan n so wipe Purofeso Yemi Oke lo so bee, kii se nkan ti EgbaLokan Agenda 2027 fowo si. Oro aladaso lasan ni, kii se ohun EgbaLokan Agenda 2027”
Abdulhakeem tun te siwaju, o ni: “EgbaLokan Agenda 2027 koi tii yi ohun pada lori wipe ọmọbibi ilẹ Ègbá ti o se fokan tan lao tele, ti ao si gbaruku ti lati de ipo gomina lodun 2027. Iru awon egba na si po jantirere bii Onarebu Sarafa Ishola, Seneto Lanre Tejuosho, Onarebu Agba Dimeji Bankole, Onarebu Kayode Amusan, ati Onarebu Bukola Olopade.
“Ao ta ko ẹnikẹni o, sùgbón gboingboin la duro sinsin leyin ilẹ Ẹgba lati de ipo olori”