Isuna owo to din die ni irinwo bilionu naira (N375.79 billion) ni gomina ipinle Ekiti, Biodun Oyebanji ti gbe kale fun ile igbimo asofin ipinle na lati bu owo lu fun odun 2025. lara awon nkan to gbajumo julo ninu isuna na ni oro ounje, eto aabo, awon nkan imuayederun ati idagbasoke oro aje ipinle na.
Gomina Oyebanji wa se e alaye wipe, ijoba yoo gbekele owo ori VAT, owo ti ijoba ba pa labele, owo osoosu latodo ijoba apapo ati be bee lo, lati le na fun isuna owo 2025 na. O fi kun oro re wipe, isuna 2025 yoo mu itesiwaju ba awon ise-akanse ijoba oun ti won ti bere lati odun 2024.
Oyebanji tenu mo o wipe isuna odun to n bo yoo se amojuto awon eto onigun mefa otooto ti o duro gege bi opo idagbasoke ipinle Ekiti. Awon opo na ni, eto iselu, idagbasoke awon odo ati pipeese ise, eto ogbin ati idagbasoke aroko, pipeese awon nkan ameyederun, idagbasoke awon osise ati imugbooro to asa, ise ati irin afe.
O fi da ile igbimo asofin ipinle na loju wipe ijoba oun yoo se amulo isuna odun 2025 lona to ba igba mu kaakiri agbaye, ati wipe ijoba yoo lo isuna na lati moju to iranwo fun awon to n sise owo tabi awon ti won o si laarin awon onise-ose tabi ise ijoba.
Gomina Oyebanji ni: “Ti eo ba gbagbe, ojo kerindinlogun osu kewaa ni mo soro nipa awon ise-akanse ti a n se lowo ati awon eyi ti a ti pari won. Iwaju ile igbimo asofin yii ni mo si ti so ekunrere oro na lojo na.
“Nkan ti a n gbero wipe ki isuna 2925 o mojuto ni awon nkan bii eeto aabo lori pipeese ounje, eto isodoro ati ire araalu. Ohun to si je wa logun ni riro awon eeyan wa lagbara lati ni imo tabi ogbon atinuda ti o wulo fun isodoro (wealth creation), pipeese ise ati siso ipinle Ekiti diibi ti awon eeyan yoo ni igbekele fun idokoowo to loorin ati igbe aye alaafia.” Gomina se afikun wipe ijoba oun yoo ro ileese to n gba owo-ori lagbara lati le pa owo wonu isuna ijoba daada.
Ninu idahun re, Agbenuso fun ile igbimo asofin ipinle Ekiti, Aribasoye Stephen Adeoye lu gomina Oyebanji l’ogo-enu fun awon orisirisi aseyori ti o ti se lati igba to de ipo gomina. O wa fi da gomina loju wipe awon yoo sa ipa awon lati rii pe, awon so isuna 2025 di ofin laipe.