Nje iwo je olugbe agbegbe Lekki-Ajah n’ipinle Eko, tabi o ti e mo enikeni l’agbegbe na, Iroyin ni lati je koko fun e ati awon eeyan re.
Aisan digbolugi tawon oloyinbo n pe ni RABIES ti di atankale l’agbegbe Lekki, debi wipe awon alakoso egbe dokita eranko torile ede Naijiria, Eka Ipinle Eko, iyen Nigerian Veterinary Medical Association (NVMA) ti ke gbajare seti awon ijoba ipinle na.
Alaga NVMA, Dr. Ofua Mark to fi ikede na lede salaye wipe, awon fidi ajakale aisan mule leyin opolopo iwadii tawon se ni National Veterinary Research Institute (NVRI) to wa nilu Vom, ipinle Plateau. Dr Mark
O fi kun oro re wipe awon ayederu dokika eranko to gba igboro kan, lo se okunfa aisan digbolugi ohun pelu bi won se n fun awon aja ati eranko miran loogun ati abere rabies lona ti ko ba liana itoju eranko mu. O ni aisi amojuto dada tabi aisi ofin to fi ese mule lori sise itoju aja ati eranbko nipinle na lo tun je ki isoro ohun tun gbile dada.
Aisan buruku ni aisan digbolugi (Rabies) je. Aja ati awon eranko miran lo ma n tan aisan kale paapajulo nigba ti won ba ge eniyan je. Aisan rabies se e toju nitooto sugbon ijamba to mu dani po pupo.
NVMA ni awon ti kowe ranse si ijoba ipinle Eko, Minisiri fun eto ogbin ati aajo to n dena itankale ajakale arun, iyen Nigeria Centre for Disease Control and Prevention (NCDC) lati ma fi ina sori orule sun lori oro na rara. Loju ese ni ijoba papa si ti bere si ni se iwadi ati ofintoto lori oro na. Koda, won ti gunle ikede ati itaniji fawon araalu wipe ki won kiyesi ara ati agbegbe won dada.
Ijoba ati NVMA wa ke si awon ara Ajah, Lekki ati be be lo, wipe ki won mojuto aja won dada, ati wipe ki won gbiyanju lati rii wipe awon gba dokita aja to kosemose lati ma a se amojuto tabi iwosan fun aja won pelu. Won tun ki won nilo wipe ki won jawo ninu fifun aja labere funra ra won.







