Ileejo kotemilorun to fi ipinle Eko se ibujokoo ti fi onte luu wipe, ko si ani-ani, idile Mabudeje gan-an lo ni eto si oye Oba Agbowa-Ikosi to wa n’Ikorodu. Ileejo na ni, Omo’ba Owolabi Saheed Momson ko lo ye ko gun ori aleefa na, notori wipe idile Mabudeje labe olori-ebi won, Omo’ba Babatunde Adenusi lo ye ki won uan omo-oye ti yoo gun ori apere na.
Adajo Ngozika Okaisabor to gbe idajo na kale (iyen CA/LAG/CV/1104/2023), bu enu ate lu igbese ati ase ti ileejo giga ipinle Eko, gbe kale lori oro na, l’eyi to faramo wipe ki Momson o te siwaju gegebi oba ilu na. Adajo Okaisabor ni asise gba-a ni ile ejo giga ohun se ninu idajo re. O ni ileejo giga tipinle Eko ose iwadi to munadoko daadaa lori oro na ko to gbe idajo re kale.
Ninu oro re, Adajo Ngozika Okaisabor ni eri to daju wa niwaju ile ejo wipe looto ati lododo, idile Mabudeje gan-an lo ni eto si oye Oba Agbowa-Ikosi . O ni, ninu eri kan ti won gbe wa siwaju ile ejo, iyen ipade awon afobaje ti won se ni odun 2007, nibe ni idile Aduloju ti soo ni gbangba wipe awon o ni nkankan se po pelu idile Oba Mabudeje.
Die ree ninu iwe ti idajo ohun wa…













