Gbajugbaja olorin emi, Bunmi Akinnanu Adeoye ti gbogbo ayé tún mo sí “Omije Oju Mi” ti jade láyé. Ale Tusidee ni awon to sun mo o, kede wipe obirin ohun ti ki aye pe ‘odigba-o-se’.
O ti to asiko diẹ ti “Omije Oju Mi” ti n se aisan ti enikan o si lo so ni pato, irufe aisan to n ba a fin’ra.
Ninu odun to koja yii (2025) ni fidio Akinnanu kan sadeede fara han lori ayelujara ninu eyi to ti n bebe fun adura awon eeyan ninu soosi G.F. David Ministries to wa n’Ibadan. Koda, awon ololufe re paapa gun le orisirisi adura lojuna ati wa ojuutu si aisan ohun, leyi to je wipe isun eje kan kan n san lati inu ese obirin na ni.
Eni odun mewaa ni Akinnanu wa, to ti yan ise orin-kiko laayo, debi wipe, nigba to to asiko kan, o kowe fi ise re sile ni ile ifowopamo to ti n sise, lati le gbaju mo ise orin emi ni kiko
Emi ologbe na koi ti fi eto isinku lede. Sugbon bo ba se je, iweroyin TheWest ko ni se alai fi to yin leti







