Gbòòrò-gbooro ni iye ìbò tí gomina Biodun Oyebanji fi fi eyin awon alatako janle ninu àbájáde eto ìdìbò gomina to wáyé nipinlẹ Ekiti lójó Sátidé.
Gẹgẹ bí ìkéde tí àjọ alamojuto ètò ìdìbò ni Nàìjíríà (INEC) ṣe nílùú Ado-Ekiti, ìbò 319, 224 ni Oyebanji to gbé àsìá ẹgbẹ APC nínú ètò ìdìbò na ri sajo lapapọ. Adijedupo latinu egbe oselu PDP, Dr. Wole Oluyede ni akojọpọ ibo 40, 543 nigbati aṣojú egbe oṣelu ADC, Dare Bejide se ipo keta. Apapọ ibo tirẹ jẹ 12, 872.
INEC tun kede wipe 6,332 ino ni àwọn ondibo fi ṣegbe latari aimatele alaale eto ìdìbò ohun. Àjọ na ni 382, 109 ni apapọ ibo t’awon eeyan di kaakiri ijoba ibile merindinlogun (16) tó wà nipinlẹ na.
Gẹgẹ bi alàkóso eto idibo ti se sọ, Prof. Adenike Oladiji, to jẹ oga àgbà (VC) Federal University of Technology, tó wà l’Akure, wọnyi ni apapọ iye ìbò ti àwọn ẹgbẹ yòókù ri sa jọ ninu eto ìdìbò na: Accord – 564; AA – 126; AAC – 195; ADP – 1,269; APP – 61; APM – 55; LP – 276; NNPP – 35; PRP – 163; SDP – 179; YPP – 98; ati ẹgbẹ oṣelu ZLP – 113.
Prof. Oladiji ni: “Níwòn ìgbà ti Biodun Abayomi Oyebanji ti egbe oṣelu APC, ti se àṣeyọrí nípa wiwa ni ibamu pelu alaale ofin, tó si tun ni ìbò to pọ jù lọ, mo kéde re gegebi olubori ati Gómìnà ti a dibo yn fun ipinle Ekiti”







