Ilé ẹjọ ko-te-mi-lorun tó fìdí kalè sílùú Abuja ti fi ontẹ lu Ògbéni Tajudeen Ibikunle Baruwa gẹgẹ bíi alága gbogboògbò fún ẹgbẹ àwọn awakọ lorilẹ èdè Nàìjíríà, ìyẹn National Union of Roads Transport Workers (NURTW).
Eyi ja sí wípé ẹyin-agbọn lásán ni alága ẹka ẹgbẹ ohun n’ipinle Eko nigba kan ri, Musiliu Akinsanya n yín àgbàdo si, nígbà to se iwuye gẹgẹbi Alága gbogboògbò fún NURTW laipẹ yìí.
Nínú ìdájọ tuntun ohun, ile-ejo ni, kò sí mimi kan tó lè mi ìdájọ ile-ejo tó n mojuto ọrọ oṣiṣẹ (National Industrial Court), lori oro na, tí wón gbé kalẹ lojo kọkànlá oṣù kẹta, odun yìí (Suit No. NICN/ABJ/263/2023.)
Ilé ẹjọ ko-te-mi-lorun ni, ofuutu-feete lásán ni ẹjọ ko-te-mi-lorun ti Najeem Usman Yasin, Tajudeen Agbede àti àwon míràn pe, lórí ìdájọ ilé ẹjọ ọrọ oṣiṣẹ. Usman ati Agbede gbe ẹjọ kan re ilé ẹjọ lati ta ko ìdájọ to fi ontẹ lu Baruwa gẹgẹbi alaga gbogboògbò NURTW.
Igbimọ onídàájọ ẹlẹni-mẹta to jókòó lórí ọrọ na, pa’nupo lati fi ontẹ lu Baruwa gẹgẹbi Alága NURTW gbogboògbò.
Nínú àkọsílẹ idajo na (Appeal No. CA/ABJ//CV/293/2024), Adájọ Hamma Akawu Barka, Nnamdi Okwy Dimgba ati Asmau Ojuolape Akanbi, ní Baruwa gangan l’olori ẹgbẹ ohun, labẹ òfin.

Kódà, ilé ẹjọ ko-te-mi-lorun pàápàá tún pàṣẹ wipe ki awọn olupẹjọ o san owó gbà-má-bínú ₦100,000 fún eni ti won pe lẹjọ.
Lásìkò ti o n ba awon akoroyin soro lojo Furaide to koja yii, Oloye Baruwa ni awada lásán ni iwuye ati ibura fun Musiliu Akinsanya (MC-Oluomo) gẹgẹbi Alága NURTW. O fi kun oro re wipe, àfojúdi àṣẹ ile-ejo ni MC-Oluomo at’awọn eeyan re gun le.
O tẹ síwájú wípé níwòn ìgbà to je pé àgbékalẹ̀ ofin ni ẹgbẹ NURTW, o di dandan ki gbogbo nkan ti ẹnikẹ́ni o baa se ninu egbe na, ko ba ilana òfin mu. Pàápàá jùlọ, yiyan oloye tabi Alága ẹgbẹ.
O wá rọ ọgá àgbà yanyan f’awon Ọlọ́pàá (IGP), Kayode Egbetokun wipe ko rii dájú wípé àṣẹ ile-ejo ni mimuse lori ọrọ na, lojuna a ti begi dina laasigbo ti iru nkan bẹẹ le mú wáyé.
E gbọ diẹ nínú ọrọ rẹ: “O je nkan iyalẹnu fun gbogbo olori ati oloye ẹgbẹ NURTW nigba ti a gbo wípé, Musiliu Akinsanya tí gbogbo aye mo si MC-Oluomo ti di Alága ẹgbẹ́ ohun ti won si bura fun lojo kọkànlá oṣù kọkànlá odun yìí.
“Eleyii jẹ àtakò ponbele ati àfojúdi àṣẹ ile-ejo National Industrial Court to to fìdí rẹ múlẹ tẹlẹ wípé Alaaji Ibikunle Tajudeen Baruwa ni yóò tuko egbe NURTW fun odun merin gbáko. Koda, èèmejì otooto ni ile ẹjọ fìdí oro na mulẹ”

O tun tẹ síwájú, o ni: “Ko sí aniani wipe Musiliu Akinsanya (MC-Oluomo) ti fúnra rẹ yọ ara rẹ kúrò ninú ẹgbẹ NURTW nigba to fa kaadi jíjẹ ọmọ ẹgbẹ ohun, ya nita gbangba lójó kẹsán oṣù keta odun 2021. Labe ofin NURTW, MC-Oluomo kii se omo-egbe awako NURTW mo latigbana.
“Ko si alafo fun ipo Alága NURTW lọwọlọwọ yìí. Bẹẹ ko si ipeese fun idibo si ipo ààrẹ, nigba to je wípé alága kan si wa lori aleefa.
“Eyi ni lati ke si IGP olopaa lorileede yii, wipe ki won ma fi owo yẹpẹrẹ mu oro na, pàápàá julo Alh. Najeem Usman Yasin, to ti figba kan je alaga egbe na, nitori wipe oun gaan ni rusida, to n wa ona alumokoroyi lati da wahala sile ninu NURTW.”