Aheso oro lorisirisi lo n lo nigboro leyin ti Sola Ayomikun, to je omo kan soso ti agba osere tiata nni, Peju Ogunmola bi fun agba osere miran, Sunday Omobolanle ti gbogbo eeyan mo si Aluwe, jade laye laipe yii.
Ibanuje nla gbaa ni iku omokunrin ohun da sile laarin awon onitiata ti gbogbo won si darapo mo Peju Ogunmola ati idile re lati ba won kedun omo won to fo sanle to si ku.
Ojo Tusidee ose yii, ni osere tiata Biola Adebayo kede iku omokunrin na loju opo ikanni ibanidore re. Sugbon. logan leyin ti iroyin iku Ayomikun bo sori ayelujara Intaneeti, orisirisi iroyin lo bere si ni tan kale lawon ikanni ibanidore Social Media kaakiri, Koda, eyi to fi ese rinle ju ni iroyin wipe, inu baluwe ni Sola Ayomikun subu si, ti o si se be di ero orun.
Wayi o, idile Peju Ogunmola ti se ikilo fawon opuro redio-eleje ti won n gbe iroyin ti oju won ko to kiri, wipe ki won jawo ninu isokuso nipa iku Sola Ayomikun.
Ninu atejade kan ti agbenuso idile na, Yemi Amodu, fi lede lojo Furaide, won ni iro nla gbaa ni wipe Ayomikun yo subu ninu baluwe n’ilu Oyinbo United Kingdom. Amodu ni, omokunrin oun paapa ko tile ku si ilu Oyinbo rara. O ni ilu Ibadan nipinle Oyo ni omo na dake si leyin aisan ranpe to se. O fi kun oro re wipe, laipe sigba na ni gbogbo ebi panupo lati sinku na.
Amodu ni: “Eyi ni lati so ni pato wipe, Sola o ku sinu baluwe, bee ni ko yo subu ninu baluwe kankan, gegebi awon alaheso oro se n so kaakiri lori ayelujara. Aisan ranpe lo se, to si gba itoju to peye lori aisan na ki olojo o to de.
“Ile Iwosan kan niluu Ibadan ni o ku si, ti a si ti sin-in.
“A wa n ro gbogbo araalu wipe ki won ko’tikun si isokuso awon iroyin-eleje ti awon kan n gbe pooyi enu, wipe Sola ku leyin ti o subu si ile-iwe ti ko si ri oluranlowo kankan lati ran an lowo.” Agbenuso fun awon molebi, Yemi Amodu lo so bee







