“Zaazu-Zeh… Ara adugbo, tuntunt ti de o!” Ede gbajugbaja olorin igbalode, Portable Omo Olalomi lo n se apejuwe ara tuntun to fe se yo lagbo’le idaraya lorilede yii, nigba ti iroyin kan hande wipe, o se e se ki awon osere tiata meji, – Lizzy Anjorin ati korikosun re nigba kan ri, Iyabo Ojo, o f’ija peeta lori odan laipe yii ninu celebrity boxing fight kan tawon kan peto re lowolowo.
Sebi eo gbagbe wipe lose to koja yii ni aderinposonu ori Social Media, Carter Efe wo sokoto kanna pelu Portable Omo Olalomi ninu celebrity boxing fight kan l’Ekoo, nibi ti Efe ti gbe’gba-oroke leyin iwodimu onipele-meta (3-round bout) tawon mejeeji se loru ojo na.
Paulo Okoye to je orekunrin Iyabo Ojo lo ti fi igba kan gbero iru ija bee laarin Lizzy ati Iyabo Ojo, to si pe Lizzy Anjorin nija lori re.
Fun eyin ti e ba n tele bi nkan se n lo lagboole tiata nile Yoruba, eo ranti wipe ore korikosun ni Ojo ati Anjorin tele ri, ko to di wipe tirela oko gba aarin won koja, ti won si d iota ojukoroju. Koda, ojoojumo lawon mejeeji fi n gbe ara won sepe, ti won si n so oko oro sira won lori Social Media.
Wayi o, Lizzy Anjorin ti gba lati gbena woju Iyabo Ojo ninu eto Celebrity Boxing Fight ti okunrin kan ti won n pe ni Paulo Okoye fe se agbekale re. Koda, Lizzy ni eru o ba oun rara o.
Die ree ninu nkan to ko sori Social Media: “Mo gba lonii, tii se ojo keta, Osu May, lati kopa ninu ija oun” O ni sugbon o, Paulo ati Oloye Lawal ni won yoo koko wodimu ko to di wipe oun ati Iyabo Ojo na yoo gbe’na woju ara won.







