Ìjọba orile-ede Saudi Arabia ti kéde wípé aawẹ Ramadan yóò bèrè lọla Sátidé lèyìn ti won ti ri òṣùpá ni orileede na.
Ọgbọn ọjọ ni awon Musulumi fi ma a n gba aawẹ Ramadan lọdọọdun l’eyi to bọ ṣi oṣù kẹsán ninú calendar àwọn Larubawa.
Ìgbàgbọ awon Musulumi si ni wipe osu Ramadan ohun lo je eyi to ni aponle julo láàrin gbogbo osu to wa lori calendar Larubawa ohun.
Wayi o, awon Musulumi orilẹ-ede Naijiria yóò ma a reti ikede lati ọdọ Sultan (Oba) Sokoto nípa yiyọ Osù ki won to bẹrẹ ààwẹ̀ tiwon.