Alága ẹgbẹ awakọ̀ tẹlẹri fún ipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti gbogbo ayé mọ si ‘MC-Oluomo’ ti di alága egbé awakọ̀ jakejado orilẹ ede yìí.
Òní ọjọ Sátidé ni wọn fi ibo gbe MC-Oluomo wọlé sipo alaga egbe NURTW nínú eto idibo kan ti egbe ohun se ni ofiisi won kan to wa lojuna Osogbo-si-Ikirun. Kódà MC-Oluomo nìkan lo gbé apoti ìdìbò ti ko si ẹnìkan to ba a f’igagbaga.
Lara awon miran ti won dibo yan ni Tajudeen Agbede gegebi igbakeji Alaga fun ẹkùn Iwo-oorun, àti Akeem Adeosun gegebi oloye alafokantan (trustee).
Nínú ọrọ rẹ gégébí alaga NURTW tuntun, McOluomo ni, gbogbo nkan tó sẹlẹ lateyinwa ti di afiseyin ti eégún n fi aso. O ni oun ti dariji gbogbo awon to se oun lateyinwa nitori wipe, alaafia ati ilosiwaju egbe NURTW lo je oun lógún.
E gbọ ọrọ rẹ: “”Emi o ni ẹnikan sínú o. Gbogbo eni to ṣẹ̀ mi lemi ti dariji. Mo sì lérò wípé gbogbo àwọn ti emi na ṣẹ̀, ni won ti dariji emi na. Gbogbo wa la ni egbe NURTW, o si di dandan ki a jumo mo ju too fun ilọsiwaju egbe.
“Ao ni gba ki awon kan o da egbe ohun ru mo wa lori”