Lootọ, gomina ipinle Osun Ademola Adélékè ti fun Ọwá Obòkun tuntun, Kabiyesi Oba Adesuyi Haastrup ni opa aṣẹ, sùgbón sibẹ, ara o r’okún, ara o r’adìyẹ pelu bi awon ìdílé oye yòókù ṣe fi àáké kori lori wípé Oba Haastrup kò yẹ láti de ipò Ọba.
Lara awon ìdílé na ni Ofokutu royal family ti ile oye Bilaro. Won ni ko sí ooto kankan nínú àhesọ ọrọ kan tó ni awon ti wogile iwé ipejo kan tawon gbe re ile-ejo lati pe Ọwá àti ìjoba ìpínlè Òsun lẹjọ.
Olori ebi ohun, Banji Obembe ninu atẹjade kan to fi lede, ni iro nla ati arekereke lásán ni iroyin wipe awon ti wogile ẹjọ ohun. O ni ko si enikan laarin ẹbi na to le gbe iru igbese na nitori ajumọṣe lawon fi ẹjọ na ṣe.
Obembe ni: “Gbogbo ẹnu la fi n sọọ wípé ko sí ootọ kankan ninu iroyin to so wipe a ti wogile ejo ti idile oba Ofokutu pe nile ejo lori yiyan ti won yan Ọwá Obòkun tuntun ti won ṣẹṣẹ yan.
“Kii se enikan ṣoṣo lo ṣe ìpinnu lati gbe ejo na re ile-ejo, fun idi èyí, ko si ẹnìkan ṣoṣo to le pinnu laaye ara rẹ lati wogile ẹjọ na. Bi iru re yóò ti e waye, a je ipinnu gbogbo ebi lapapọ.”
Obembe tun te síwájú, o ni awon ni igboya ninu ile ejo lati da ejo na bo ti to, ati bo ti ye.
“A n fi akoko yi ro araalu wipe ki won ma ka iru iroyin bẹẹ si rara. O da wa loju wipe daada ni ọsan yóò so fun wa nile Ẹjọ, ti ao si pada gba ipo Ọba to tọ si idile wa.”
Koda, Obembe tun ṣàlàyé wipe ẹjọ ko ni nkankan ṣe pọ pẹlú awon “Agba Ijesa,” o ni bi oye ọba to tọ si idile awon ni ẹjọ ohun da le lori.