Ẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ẹka t’ipinle Osun ti fi àrokò ranṣẹ si Gómìnà Ademola Adeleke wípé, ko má da ara rẹ láàmú wipe òun fẹ darapọ mọ APC nítorí wípé ko si aaye fun un ninu ẹgbẹ ohun.
APC ni ko ba ara rẹ dà s’ohun nítorí ko sí ànfààní kankan to wa lara Adélékè fún ẹgbẹ APC paapajulo pelu bi ipinle na se n mura sile fun eto idibo gomina lodun 2026.
Laipe yii ni iroyin kan lalẹhu káàkiri ipinle Osun wipe gomina Adélékè ti dìgbà-d’agbon ni imurasilẹ lati darapọ mo ẹgbẹ oselu APC. Kódà, awon kan ninu ẹgbẹ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) tiẹ sọ pé awon ṣetan lati tẹle Adélékè lo sinu ẹgbẹ APC.
Sugbon alaga APC n’ipinle na, Sooko Tajudeen Lawal, ninu atejade kan, tẹnu mọ ọ, wipe egbe awon ko Adélékè paapajulo nítorí isekuse to n se owó ilu n’ipinle Osun, ati kudiẹ kudiẹ ti Adélékè yóò ko ba egbe APC gegebi ọmọ ẹgbẹ. O ni fun idi eyi, awọn kọ ọ.
Diẹ ree ninu oro to wa ninu atejade Lawal to te iwe ìròyìn TheWest lọwọ. O ni: “Bo tile je wipe lóòtó ni òfin fáráyé gba ẹnikẹni lati darapọ tabi lati kúrò ninu ẹgbẹ òṣèlú kankan, ẹgbẹ APC kii se akitan ti wọn kan lea a da idọti orisirisi si, bii àwọn olóṣèlú ti wọn n fi iwonwora wa ibi ti won le sa pamọ́ si, gẹgẹbi ogunlende.
“Inakuna ti Adélékè na owó to fere to trillion naira kan (N1tr) laarin ọgbọn-oṣù lásán, pelu N13bn tona lori ọkọ-bogini fun awon òṣìṣẹ́ rẹ, ti se akoba to pọ fún ipinlẹ Ọsun.”
Alaga APC n’ipinle Ọsun ló sọ bẹẹ.
O fi kun ọrọ rẹ wipe, ko si nkan meji ti Adélékè ṣe n sá káàkiri ju wipe, o n wa ona abayọ si bi noam se dojuru fun, lojuna ati wole gomina fún sáà keji. O ni oju-aye lasan ni gomina na n se nigba to fi onte lu ààrẹ Bola Tinubu fún sáà keji.
Ṣugbọn isoro ni’gbesi no ẹgbẹ PDP fi ọrọ na ṣe. Awon gan paapa ti ju oko oro si Lawal lori ogulutu to sọ.
PDP ni digbin lawon wa fun eto Ìdìbò odun 2026.
Alaga ẹgbẹ́ na n’ipinle Osun, Onarebu Sunday Bisi, na fi atejade lede, ninu eyi to ti n sọ wipe APC kan n wa àwáwí asán ni, awon o si se tan lati ba wọn ni àríyànjiyàn kankan nítorí o han gedegbe wipe awon aráàlú n fe ti Adélékè pelu awon ise amayederun lorisirisi to ti se latigba to ti dori aleefa bi Gomina ipinlẹ Ọsun.