Okan nínú àwọn tíṣà (olukọ) ti won ji gbe nílùú Esinele, létí Ogbomoso n’ipinle Òyó, Rachael Alamu tí bẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà wípé kí wọn jáwọ nínú gbígbé ìròyìn ofegee kiri lori ọrọ Ìjínigbé to waye láwọn ileewe l’agbegbe na nínú oṣù kàrún.
Alamu ni ko si ooto kankan nínú awon nkan ti awọn kan n gbe kiri wipe awon bandiiti ohun n bere owo (₦1bn) ati ayípadà ofin lati faaye gba Sharia.Tíṣà na sàlàyé wipe, iru awon iroyin bẹ kan n se akoba fun awon tawon wa lakata awon ajinigbe ohun.
Nínú fidio tuntun ti won sese fi lede, ni Àlàmú ti n ṣe e lalaye wipe nkan eyokan pere láwọn bandiiti na n bere. Ohun si ni wipe ki ijoba o tu awon eeyan won to wà latimole sílẹ ni kíá.
Bi eo ba gbagbé, ọjọ keedogun oṣù karun (15th May) ni awon agbébọn yà wọ awon ileewe bii meta ni Esin ele ati Yawota, ti won si se be ko àwon akékòó ati awon tíṣà wọn sá wọ inú igbó lọ.
Títí di àsìkò yìí, ko tii sí ẹnikan tó lè sọ ní pàtó, wípé ibi báyìí ni won ko won pamọ́ si.Ṣugbọn sá, laipe yìí ni iroyin kan tàn kalẹ lori ayelujara wipe awon bandiiti na n bere fun orisirisi nkan.







