Awon àgbààgbà ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọyọ ti fi ìmọ ṣọkan lórí ọmọ oyè tàwọn yóò fa kalẹ lati dijedupo Gómìnà nipinlẹ na, ninu eto idibo ọdún to n bọ. Ọjọ wesidee ni wọn panupọ láti fa ọwọ Sínétọ̀ Sharafadeen Alli sókè gẹgẹbi ẹni ti yóò ṣe aṣojú ẹgbẹ APC.
O ṣe e ṣe ki igbese yìí o pa’ná awuyewuye to n ti n ja ranyin-ranyin laarin awọn oloṣelu ẹgbẹ APC nipinlẹ na lori ta lo ye ko gbé àsìá ẹgbẹ na ninu eto idibo gomina.
Lára àwọn tí ọrọ na kan ni mínísítà ana fun eto iná-ọba lorile-ede yii, Adebayo Adelabu (Penkele), adijedupo gomina lodun 2023, Sínétọ̀ Teslim Folarin, Sínétọ̀ Abdulfatai Buhari, igbákejì gomina tẹlẹ ri, Injinia Rauf Olaniyan, Adéwálé Kolapo Aremu, Amofin Akeem Agbaje, ati be bẹ lọ.
Kódà, ọpọlọpọ wọn lo ti n sọ wipe, a fi ki egbe o ṣe eto idibo abele lati fi yan ọmọ oyè nítorí awon o faramọ àṣà “BABASOPE” tí won yoo kan fa ọwọ enikan sókè laise wipe gbogbo ọmọ ẹgbẹ ló yan an.
Ṣugbọn l’ojo wesidee nínú gbongan Prof. Theophilus Ogunlesi, tó wà ní University College Hospital (UCH), ni Ibadan, awọn àgbààgbà egbe kede wipe, leyin ti awon ti ṣe ìwádìí ati iforojomitoro-oro pelu awon leekan-leekan ninu egbe ohun, awon panupọ lati yan Sínétọ̀ Sharafadeen Alli gẹgẹ bi ọmọ oyè laisi alatako, iyen consensus candidate.
Lásìkò tó n sọrọ níbi ipade ohun, alàgbà Alarape Jolaoso ni, awon ti gba aṣẹ lati ọdọ ààrẹ Bọla Tinubu lati lọ fa ọwọ Alli soke nita gbangba gẹgẹbi adijedupo fun APC ninu eto idibo gomina ọdún 2027 nipinlẹ Ọyọ.

Ṣebi eo gbagbe wipe laipe yii ni Adelabu fi esun kan àwọn olori egbe ati Alli wipe, ko sí ooto kankan nínú ọrọ ti wọn sọ wipe Ààrẹ Tinubu lo yan Alli gegebi okanlawon adijedupo.
Ṣugbọn alagba Sínétọ̀ Ayoade Adeseun, tóun na wa nibi ipade ọjọ wesidee ni, ẹkọ ti pada fojú mimu han, lori ọrọ ohun, pelu bi Tinubu se fi ontẹ luu.
Alhaji Fatai Ibikunle pàápàá tẹnu mọọ wipe, ko sí aniani mo, wipe Tinubu ti fi ọwọ sí yíyan Sarafadeen Alli. O ni ko s’ọrọ mọ lórí tikeeti gomina APC ìpínlè Òyó.
O wa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lapapọ at’awọn ti kadara o se loore lori tikeeti ohun wipe, ki won fi ọwọ so’wopo lati le gbe Sharafadeen Alli de ipò Gomina ipinle Oyo.
Alli pàápàá tóun na wa nibi ipade na, dupẹ lọwọ ààrẹ Tinubu at’awọn ẹgbẹ APC, o si se ileri wipe oun o ni ja wọn kule rara, lojun a ti di gomina ipinle na.
Lára awon to wa nibi Ipade ohun ni Alhaja Tinuade Adigun, Alhaji Mojeed Olaoya, Apoostu Aderounmu, Olóyè Francis Babalola, Olóyè Yemi Aderibigbe, Dr. Tunji Olanipekun, Awọn Ọnarébù bii Aderemi Oseni, Akeem Adeyemi, Akeem Akogun, Akin Alabi, Saheed Alaran, Shina Alabi, ati Tolulope Akande-Sadipe. Awon yooku ni: MKO Laoye, Hannah Ogunesan, Olamijuwonlo Alao-Akala ati alàgbà Olu Akintola.
Títí di àsìkò ti a fi n ko ìròyìn yìí jo, alagba Adelabu o tii so nkankan sí ọrọ na.








