Lẹsẹkẹṣẹ tí alága àjọ alabojuto ètò ìdìbò Lorile-ede Nàìjíríà, Purofeso Mahmood Yakubu gbé ìṣàkóso àjọ INEC sílẹ, ni ile ẹjọ ìjọba àpapọ kan to fi ilu Osogbo ṣe ibùjókòó paa lasẹ wípé ki oga àgbà ọlọ́pàá Kayode Egbetokun o fi ọwọ sinkun òfin mu ọmowé Yakubu.
Ẹsẹ ti alága INEC àna na ṣẹ ko ju wipe,.o fi ojú di aṣẹ ile-ejo to ni ko ṣe àtẹ̀jade orukọ alaga ẹgbẹ́ òṣèlú Action Alliance (AA), Adekunle Rufai Omoaje ati awon ọmọ ẹgbẹ òṣèlú na, lori atẹ to je ti INEC.
Ṣugbọn, won ni, nise ni Yakubu koti ogboin si ase ile-ejo na, to si ko jale lati se gẹgẹ bi aṣẹ ohun.
Adájọ Funmilola Demi-Ajayi lo pa ase ti Yakubu ko lati muse latari ejo ti alaga ati àwọn ọmọ ẹgbẹ AA pe INEC.