Ààrẹ Bola Tinubu ti sọ ìwé abadofin ìṣúná owó ọdun 2025 di òfin ni kíkún, lẹyìn ìgbà tó bu ọwọ́ lu ìwé òhún l’ọsan òní Furaide, nílùú Abùjá.
Apapọ owó tó wà ninú ìwé ìṣúná na jẹ N54.99tn lẹyìn ti awon aṣòfin ti ṣe afikun owó na lati N49.7tn tó wà tẹlẹ ri.
Àfikún na wáyé latari afojusun ìjọba lórí owó ti wọn n reti wípé yóò wolè lati ilé-isé to n gba owo-ori fun ìjọba (FIRS) ati awon miiran bíi ileese asobode Customs.
Lára awon nkan ti ìṣúná na yóò mojuto ni eto aabo, eto ilera, ètò èkó ati awon nkan amayederun míràn lorisirisi.
Bi eo ba gbagbe, N27.5tn pere lo wa ninú ìwé ìṣúná owó t’odun 2024. O ja si wípé nkan bii 99% (igbelogorun merindinlogorun) ni ìṣúná 2025 fi gbe peeli jù ìṣúná 2024 lọ.
Lára àwon tó wà ni’bi ayẹyẹ ibuwoluwe ohun l’Abuja ni awon leekanleekan oṣiṣẹ ìjọba àti awọn olori ile igbimọ aṣofin méjèèjì.