Ojo kefa, Osu kefa (June 6) ni Odun Ileya yoo ma a waye jakejado agbaye. Ijoba orile-ede Saudi lo fi Ikede na l’ede, pelu alaale awon eto yooku to saba ma n ba odun ileya rin.
Ninu atejade ti Haramain Sharifain fi sori ikanni Ibanidore X ti a mo si Twitter tele ri, ijoba Saudi ni, ojo Wesidee May 28, 2025 ni Dhul Hijjah 1446 yoo bere.
Eyi je osu kejila ninu odun awon Larubawa, o si je okan ninu awon osu merin ti won kii fi ja’gun, asiko yii na ni won ma a n se Hajj pelu. Koda, won ni awon ti fi oju kan osupa to ma je gege bi atoka si ibere osu Dhul Hijjah ohun.
Gegebi ikede na ti se salaye, ojo karun osu kefa ni ojo Arafa, iyen ojo ti awon Alalaaji yoo gun oke Arafa. Ojo keji re l’odun ileya paapaa, leyi to n ran awon Musulumi leti irubo ti Anabi Ibrahim fe fi omo re se, ki Allah to fi agbo funfun ropo re.
Bi awon Alalaaji se n gun Arafa na ni won yoo ma a gbadura wipe “Labbayk Allahumma Labbayk, Labbayk la sharika laka Labbayk. Innal Hamda, Wannimata, Laka Wal-Mulk, La Sharika Lak.” Itumo eyi to je: “Emi na ree, Allah. Emi ree, Iwo ti o ni igbakeji, Emi ree o. Looto-looto, ola ati gbogbo agbara nbe lodo re, bee, o o si ni igbakeji…”