Iléesẹ́ to n mojuto igbokegbodo ọkọ ofurufu lorilede Nàìjíríà, ìyẹn Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA) ti fi ofin de ilumooka olorin fuji nni, Wasiu Ayinde K1, wípé oṣù mẹfa gbáko ni ko fi ni l’Anfaani lati fo nínú oko-ofurufu kankan nibikankan lorile ede Nàìjíríà.
Ìdájọ yii wáyé latari ìwà tani-yoo-mumi ti Wasiu Ayinde hu lójó Wesidee ose yii lásìkò to fe wọ ọkọ ofurufu ti Value-Jet ni papako ofurufu ti Nnamdi Azikiwe International, to wa l’Abuja.
Gegebi ẹsun ti won fi kan K1, olorin fuji na gbe igo kan dání, ti wọn ni ọti lo ro sinu re, leyi ti ofin ko fi ààyè gbà lati gbé wọ inu ọkọ ofurufu. Bó tilẹ je wipe Wasiu pàápàá yari wípé kii se oti loun to sinu igo na, o ko jalè lati je ki àwọn osise ààbò to wa níbẹ o ye nkan ohun wo, ki won le fi idi re mule pe looto ni kii se oti.
Ẹnu òrò yii ni won wa, ti Wasiu ti da gbogbo re si agidi, to si bere si ni huwa tani-yoo-mumi, debi wipe o duro siwaju oko ofurufu Value-Jet Flight VK201 to fe gbera, wipe oun o ni gba ki oko na o gbera laise pe oun wọ’nu rẹ.
Koda, fónrán fídíò kan to wa lori ayelujara se afihan ìwà jagidijagan ti àgbà osere na hu, tàwọn kan si n sọ wípé, nítorí o je ọrẹ ààrẹ Bola Tinubu ni o fi n hu iwa kò-tọ ohun.
Wayi o, leyin ti NCAA ti fi iya to tọ je awon awako ofuurufu ohun nítorí pe won gbera lai gba ase lati gbera, won tun ti fi ofin de Wasiu Ayinde wípe orí ilẹ’lẹ ni yóò ti ma a rin irin ajo re fun osu mefa gbako, ati wipe awon o gbodo keefin rẹ lagbegbe papako ofurufu kankan jakejado Nàìjíríà.