Laipe yii l’awon omo Naijiria kakkiri awon ipinle kan sadeede rii wipe gaasi idana ti di goolu ti awon eeyan n wa kiri. Koda, biba l’awon ero n to si ile epo tabi ibudo ti won ti n ra gaasi idana ki won to le rii ra. Bee, awon ti won rii ra paapa, owo goboi ni won san ki won to ri kini ohun ra lo sile koowa.
Saaju asiko yii, awon araalu n ra kilo gaasi kan ni nkan bii ₦1,200 si ₦1,300 sugbon lowolowo bayii, O kere ju, ₦2000 ni won n ta kilo gaasi kan lopolopo awon ibudo ti won ti n taa kaakiri ipinle Eko, Ogun ati awon ibomiran ti iko akoroyin TheWest de.
Orisirisi l’awon eeyan si n so kiri wipe o fa bi gaasi se wa di goolu lojiji. B’awon kan se n so wipe, idasesile egbe PENGASSAN (awon osise epo robi) laipe yii lo faa, bee l’awon kan n so wipe ijoba fe da ogbon lati se ekunwo gaasi idana ni.
Sugbon, wayi o, awon alagbata gaasi lorile ede yii ti siso lori asiri to wa nidi owongogo gaasi idana. Awon egbe kan to nii se pelu gaasi lorisirisi nile Naijiria, iyen Nigerian Association of Liquefied Petroleum Gas Marketers (NALPGAM) ti se afomo oro. Won ni oro o ri bi awon eeyan se n so yen. Won ni wiwon ti gaasi won, ko ni nkankan se pelu wipe ijoba fe fi owo kun iye ti won n taa saaju asiko yii.
L’asiko to n soro lori eto telifisan kan l’Ekoo lojo Wesidee, Aare egbe ohun, Oladapo Olatunbosun se alaye wipe owongogo ohun kii se nkan ti yoo pe rara, nitori wipe awon arijenidimadaru alagbata gaasi ni won kan d’ogbon lati hu iwa makaruru nipa fifi owo kun iyen ti won n ta gaasi fawon araalu.
O ni awon onijekuje algabata na, kan lo anfaani aawo to wa laarin ileese ifopo Dangote ati PENGASSAN lati fi pawo wole sapo ara won lona eeru ni.
Olatunbosun ni: “Mo ba awon omo Naijiria kedun owongogo gaasi ti won n koju lowo, nitori wipe, ko si ninu erongba wa wipe iru nkan bayii yo waye lasiko yii rara. E je ki n soo taara wipe gaasi idana ko gbe owo lori rara. Ko si akosile kankan tabi ajosoyepo kankan to ni ao se afikun owo ti a n ta gaasi idana.
“Nkan to n sele ni wipe, awon alagbata kan ni won wa nidi oro na. Ni logan ti won rii wipe, awon ti won pin gaasi o fi bee pin-in daada bi ti ateyinwa, ni won ba sare se afikun gaasi to wa lorigba won tele.
“Sugbon, mo fi n da yin loju wipe, laipe gbogbo nkan yo pada bo sipo nipa owo gaasi idana. Koda, ko ni pe mo” Olatunbosun lo soro idaniloju ohun







