Iyalẹnu lọrọ ohun jẹ fún gbogbo àwọn tó wà níbè lójó Furaide tó kọja yii nigba ti ile-ejo Majisreeti kan to wa n’Ikeja bẹrẹ igbejo awọn ọkunrin meji kan, ti wọn fi esun kan wípé wọn n ko ayédèrú rọba ìdáàbòbò Kondomu wọlé s’orile ede Naijiria fun tita, to si n pa awon èèyàn lára.
Emeka Daniel ti ọjọ ori rẹ jẹ 32 ati Ugochukwu Eze, ẹni ọdún marundinlogoji (35) ni wọn káwọ pọn’yin níwájú adájọ Lateef Owolabi lórí ẹsun wípé wọn n gba ònà eburu lati ma a ta gbarogudu Kondomu KISS fun aráàlú gẹgẹ bi ojulowo.
Gégébí ọgá olópàá to wa nidi ẹjọ na, Josephine Ikhayere ti ṣẹ sọ, ọjọ ketalelogun osu kefa (June 23rd) ni ọwọ ba Emeka àti Ugochukwu nígbà ti wọn ko àwọn Kondomu ayédèrú ohun wole sorile-ede Naijiria.
Ikhayere ni, bo tilẹ jẹ wípé àwọn yòókù ti won jọ n se owo to lodi s’ofin ohun, ti f’ẹsẹ fẹ, awọn méjèèjì ti owo ba, ko b’esubẹgba lati ma a se àkóbá fún awon aráàlú nítorí wipe wọn mọ daju wipe Kondomu Kiss ti wọn n ta kii se ojúlówó.
Awon afurasi meji ohun wá so fun ile-ejo wípé awon o jebi ẹsun ti won fi kan won, sugbon oga olópàá na ni, ìwà ti won hu lodi si ofin iwa òdaran ti ìpínlẹ̀ Eko t’ọdun 2015, ipele 97, 362 ati 412.
Adájọ Owolabi wa pàṣẹ wípé ki awon afurasi méjèèjì o san owo beeli ti iye re je N500,000 lọkọọkan, ki won si mú oniduro mejimeji wa.
Ẹjọ na n te síwájú láìpé.