Òwe “dan an wò, ló bi ìyá Òkéré” ni adajọ àgbà f’orilẹ-ede Naijiria tó tún jẹ́ mínísítà fún ètò idajọ, Lateef Fagbemi n pa f’awon Gómìnà tó bá f’owo kan owó ìjọba ìbílẹ̀ to wa nipinle wọn. O ni òun kò ni bèṣù-bẹgba láti sin iru Gómìnà bẹẹ de bebe ẹwọn.
Ṣèbí eo gbàgbé wípé láìpé yìí ni ile-ejo to ga ju ni Nàìjíríà, -Supreme Court paá lase wípé ki àwọn ìjọba ibilẹ o wa l’ominira arà wọn, pàápàá jùlọ lórí eti isuna owó won. O ni ko si nkan to kan Gómìnà pelu owó ìjọba ibilẹ.
Ọjọ Tosidee ọsẹ yìí ni Fagbemi sòrò ìkìlọ na, l’Abuja lásìkò to n ba àwọn akoroyin sọrọ. O ni gbonmo-gbonmo taa ran’fa aditi l’oun n f’oro na se, nítorí wípé kò si ẹnikẹni to gbọdọ fi owo pa idà ofin lójú.
Fagbemi tẹ síwájú wípé, ayojuran awon Gómìnà sínú owo ijoba ibile ti se àkóbá tó pọ fún ìṣèjọba tó sunmọ aráàlú julọ. O ni ṣùgbọ́n, àṣẹ ile-ejo Supreme Court yìí, yóò mú ki àlàáfíà o padà si ijoba ibile káàkiri orilẹ ede yii.
E gbọ ọrọ l’atenu fagbemi: “Ko si ọna-kọna ti ẹnikẹni le gba lati dojú idajo tabi àṣẹ ile-ejo kọ’le, ti onitoun o ni ba ijangbon pade. Bi eye ba se lo, na lao se so oko re. Sùgbón ki àwọn alága ijọba ibilẹ ati kanselo ma gbàgbé wipe awon Gómìnà ni idaabobo imuniti ni tiwon sùgbọ́n eyi to ba wu won ni ki won o se o. Sùgbón ẹnikẹni to ba ti owo bo inu owo ijoba ibilẹ, ẹwọn ni oluwa re fi n seré. Eyi to ba wu won ni ki won ṣe.
“Gómìnà to ba wu lati fi ẹwọn gbara, le t’owo bọ owó ijoba ibilẹ. Eyi to ba wu won ni ki won se.
“To ba si wu won, won a gbe igbese lati da awon eto ìjọba ibile pada fun won, bii kiko ileewe, ile-iwosan, oja ati bee bẹ lọ to jẹ ojúṣe ijoba ibilẹ.” Fagbemi lo n sọrọ bẹẹ