Lati Owo: Abo Oyeade
Eeyan marun otooto lo je Olorun n’ipe lojo Tosidee ti awon marun miran si f’ara pa ninu ijamba oko kan to sele loju ona Epe si Lekki, n’Ipinle Eko. Poroporo l’omije n bo loju awon eeyan ti isele na soju won.
Gegebi agbenuso ileese to n mojuto igbokegbodo oko l’Ekoo, iyen Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), Adebayo Taofiq ti se se alaye, agbegbe ibudoko Abijo ni isele akoko ti sele, nigba ti oko Mitsubishi kan (AKD 733 JM) to n sa ere asapojude fi ori so oko awon osise kan to duro ni tire, si eba ona, labe afara elese kan to wa nibe.
Taofiq ni eeyan merin otooto ni won gb’emi mi loju ese nibi isele akoko ohun, -iyen okurin meta ati obinrin kan.
O fi kun oro re wipe isele elekeeji sele lagbegbe Frajend ni Bogije loju ona Epe si Lekki kanna. O ni gele bi isele alakoko, nani isele ekeji nitori wipe oko kan na loun na fi ori so oko miran ti paaki s’egbe kan. Loju ese, ni dereba oko ohun terigbaso.
Awon meji miran to wa ninu oko ohun paapa fi ara pa yannayanna, ti o si soro fun won lati kuro ninu oko ohun, funra alara won. Opelope awon iko LASTMA to ran won lowo lati gbe won jade kuro ninu oko ohun.
Agbenuso LASTMA se alaye wipe: “Ibanuje gbaa loro ohun je fun ileese LASTMA, paapajulo oga-agba LASTMA, , Olalekan Bakare-Oki, ti o fi edun okan han si awon molebi awon to padanu emi won ninu awon isele aburu ohun. Oga wa, Bakare-Oki wa ke si awon araalu wipe ki won se jeje, ki won si jawo ninu ere asapajude lawon ojuna popo kaakiri ipinle Eko.”
Taofiq tun wa ro awon araalu wipe, ki won ma jafira lati fi iroyin pajawiri nipa lilobibo oko loju popo to ajo LASTMA leti. O ni won le pe sori 0800 00 527 862 lati ba LASTMA s’oro