Fọfọọfọ n’ilu Ìbàdàn kún lójó Furaide yii lásìkò ti gomina teleri n’ipinle Oyo, Oba Rasidi Adewolu Ladoja gba adé gẹgẹ bi Olúbàdàn kerinlelogoji (44th) ti yoo gun orí aleefa na.
Ayẹyẹ igb’ade Kabiyesi dun, o si larinrin pelu bi awon leekan-leekan, tolori-telemu se pejo sibi ayeye ohun ni ori-oke Mapo, ti won si wo orísirísi aṣọ imurode to ba igba ati àṣà Yorúbá mu.
Ṣáájú igb’ade Kábíyèsí ni wọn ti já ewe-akoko le bàbá na lórí lojubo Ose Meji to wa ni agboole Labosinde, Oja’ba.
Lehin eyi ni Gómìnà ipinle na, Injinia Seyi Makinde gbé ọpa àṣẹ le Olúbàdàn tuntun lọwọ ni deede aago meta koja iseju marun (3:05pm).
Nínú ọrọ re, Gómìnà Makinde sọ pe opa àṣẹ ohun lo fi ontẹ luu wípé ki Oba Ladoja o ma a pàṣẹ gegebi Olubadan t’ile Ibadan.
E gbọ nkan to wi: “Nípasẹ àṣẹ ti a fi fun mu gẹgẹ bi Gómìnà ipinle Òyó, mo fi akoko yii gbe opa ase yii fun Oba, Sineto, Gomina, Injinia, Baba mi, Alayeluwa, Rasidi Adewolu Ladoja, Arusa Akọkọ.
“Eleyii lo fi ontẹ luu gẹgẹbi Olúbàdàn kerinlelogoji”
Ipo Olúbàdàn kan Oba Ladoja lẹyìn ipapoda Olúbàdàn ana, Oba Owolabi Olakuleh, lójó keje, Osu Keje Odun 2025.
Lara awon leekan-leekan to pesr sibi ignade ohun ni Aare Bola Tinubu, Alaafin ti Oyo, Oba Abimbola Owoade, Soun ti Ogbomoso, Oba Ghandi Ọlaoye, Gomina ana nipinle Ogun, Sineto Ibikunle Amosun, ati Imaamu agba ti ile Ibadan.