Àjọ olómìnira alamojuto ètò Ìdìbò ni Naijiria, INEC sọ pé, àwọn o tii lè fi orúkọ ẹgbẹ òṣèlú tuntun, -iyen All Democratic Alliance (ADA) silẹ gẹgẹbi ojúlówó ẹgbẹ òṣèlú labe ofin orile-ede yii.
Bí eo bá gbàgbé, láìpé yii ni àwọn olóṣèlú alatakò bíi ìgbákejì ààrẹ teleri, Atiku Abubakar, Mínísítà labe ààrẹ Mùhámádù Buhari, Rotimi Amaechi ati Gómìnà ana fun ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ko ara wọn jọ láti lè ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ oselu tuntun, ADA.
Èyí lo mu won kọ leta si ajo INEC wípé ki won gba ẹgbẹ awon na wọlé gegebi ẹgbẹ òṣèlú tí yóò ma a dijedupo nínú awon eto Ìdìbò káàkiri Nàìjíríà.
Wayi o, INEC ni, awon o le gba ẹgbẹ ADA wọlé nítorí wípé won kunna lati ni awon nkan àmúyẹ ti ofin nbere ki ẹgbẹ kankan to di ẹgbẹ oselu ponbele.
Sam Olumekun, to jẹ Komisana ni ajo INEC to si tun alaga fún igbimo to n se kookaari ifinimona fun awon ondibo, lo so oro na lakoko to n ba awon akoroyin soro l’Abuja.
O ni kii se ADA nikan ni koi ti kun oju osunwon to labe ofin, nítorí wipe ọpọlọpọ awon ẹgbẹ miran na nbe nile tawon na ti kọwe si INEC ṣugbọn ti awon na koiti kun oju osunwon dáadáa.
Olumekun ni, o ye ki ADA o kókó rii daju wipe awọn ṣe nkan ti ofin laale fun egbe òṣèlú ki won to ko leta ránṣẹ si ajo INEC.







