Ileese Olopaa Naijiria ni awon ti fi owo sinkun ofin mu awon olopaa kan ti won fi esun kan wipe won n bere owo lowo awon molebi omodebinrin kan ti awon gbomo-gbomo ji gbe niluu Ota, ipinle Ogun, ki won to le gun le itopinpin lati gba omo na sile kuro ninu igbekun.
Ojo Tusidee to koja yii ni okunrin kan to je onibara arabirin kan to n se owo POS ladugbo Sango Ota, lo ogbon alumokoroyi lati ji omo obinrin ohun, Mercy Akande gbe. Awon ti oro na se oju won so wipe, okunrin ajinigbe ohun tan omodebinrin omoodun meje na wipe oun fe ran an nise, leyin to ti ra ounje fun un.
Sugbon nigba ti awon eeyan omodebinrin na mu oro na lo si odo awon olopaa, ni awon agbofinro na ni o di dandan ki awon molebi re san N10,000 lati si faili fun oro na ni Police Station, ati N30,000 lati le to bere itopinpin number telifoonu okunrin ohun.

Wayi o, alukoro gbogboogbo fun ileese Olopaa, Muyiwa Adejobi, ni owo ti ba awon olopaa to bere owo na, bee ni won si ti so won si atimole ni kia. Bo tile je wipe ko daruko awon olopaa ohun ni pato, Adejobi fi da araalu loju wipe awon yoo se awari omodebirin ti won jigbe ohun laipe.
E gbo oro to ko si oju opo ikanni ibanidore re, X laaro Satide: “Awon olopaa ti won ni beere owo ki won to le sise iwadi ati awari omodebirin ti won jigbe na, ni owo ti ba, ti won si ti ti won mo’le. A bu enu ate lu iru iwa bee laarin olopaa, ao si ni fi aaye gba-a. Ko b’oju mu, o se’ni laanu gidi. A ro awon molebi omobirin na na wipe, ki won fi owo sowopo pelu olopaa lati le wa ojuutu si oro na”