Ilumọọka Oníwáàsí Musulumi, Aafa Muhydeen Ajani Bello ti tẹrigbaṣọ. Oníwáàsí ẹgbẹ rẹ, Sheikh Akewugbagold Taofeek, to fi ìbàdàn ṣe ibùgbé lo kede iku Aafa Bello lori ikanni ibanidore Facebook lójó Furaide
O ni: “Òní jẹ ọkan nínú awon ọjọ tí mo banuje jùlọ. Bàbá ati awokọṣe mi, ti padà sọdọ ẹlẹdàá rẹ. Sultonul Wahizeen ti gbogbo ilẹ Yorùbá lapapọ, Sheikh Muhyideen Ajani Bello. Ki Allah o yọnu si èmí rè, ko si fi Aljannah fridaos dao lola. Ọkàn wa n poruuru ìbànújẹ, ojú wa si kun fun omijé ṣugbọn eyi ko ja si nkankan niwaju eni to ni emi ati aaye lodo, iyen Ọlọrun Oba Allah.” Akewugbagold lo n se idaro bee.
Ẹwẹ, okan ninu omi olóògbé, Basit Olanrewaju Katibi Bello, ti gbogbo aye mo si Aponle Anobi, na kede iku baba re lori ikanni ayelujara laaro Furaide bakanna.
Odun 1940 ni won bi Sheikh Muyideen Bello lagboole Arolu ni Ita Olukoyi, niluu Ibadan.