Mewaa n sele l’orile ede Naijiria. Okunrin kan ree to je Mokaliki atunokose, eni odun mejidinlogbon (28) ti ile-ejo ju si ewon odun meta pelu ise asekara l’Osogbo. Kini ese ti Akeem Jimoh se gan ni pato? Isu metadinlogun (17 tubers of yam) ni won ni Akeem ji ko nilu Osogbo. Iye re si je N35,000 lapapo.
Lojo Wesidee ose yii, nibi igbejo Akeem ni Mokaliki na ti jewo wipe looto l’oun ji isu na ko, sugbon ebi lo n pa oun t’oun fi hu iwa aito na. Adajo Majisireeti, Muibah Olatunji, o fi akoko sofo rara. Logan lo ni ki won ju Akeem s’ewon odun meta gbako pelu ise asekara. Koda, adajo ko lati fun Akeem l’anfaani sisan owo-itanran.
Sugbon, Loya Ajafetomoniyan, , Femi Falana, SAN yari wipe, ijiya ti ile-ejo fun Akeem ti po ju ese to se lo. O ni, ko ye ki Naijiria ma a fi Sango wa abere to ba s’onu, nitori wipe, nkan to s’onu o to nkan ti a fi n waa.
Alagba Falana ni, idajo na ku-die-kaato, nitori wipe ko ti e fi ti edun tabi omoniyan se rara, bee na lo si ja si inakuna owo.
E gbo die ninu oro Falana: “O ti to akoko ki Naijiria ma a fi aanu ati ikedun omoniyan se ki won to se idajo. Nje o mu opolo dani wipe ki ijoba o ma a na owo ilu ni anadanu nipa fi fi bo elewon to ji ounje ti iye ko ju N35,000 lo?
“O ye ki awon adajo ati awon Majisireeti o ti mo wipe, awon orileede miran lagbaye ti fi idi re mule wipe kii se ese mo, fun eni ti ebi n pa lati ji ounje ti yoo fi bo ara re tabi idile re paapa.
“Ju gbogbo re lo, a ti gbe awon Loya kan dide lati lo kowe kotemilorun lori idajo na, paapa julo lori odun meta ti won ni ki Akeem o lo lo l’ewon.” Falana lo soro bee