Ààrẹ Bola Tinubu ti fi àmì ẹ̀yẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dá àwọn agbábóòlù Super Falcons, l’ọla fún piperegede ti peregede nínú ìdíje bóòlù obirin ni Áfíríkà (WAFCON). lorilede Morocco. Bẹẹ na ni ààre tun dá àwọn akonimoogba ati awọn oṣiṣẹ míràn nínú ẹgbẹ na lọla.
Olúkúlùkù agbábọ́ọ̀lù gba àmì ẹ̀yẹ Officer of the Order of the Niger (OON), ilé oníyàrá mẹ́ta ní Renewed Hope Estate l’Abuja, àti ẹ̀bùn owó $100,000. Àwọn òṣìṣẹ́ ati akoni-moogba náà tún gba $50,000 lẹyọkọ̀ọ̀kan.
Ibi ayẹyẹ imoriri pàtàkì kan tí wọ́n ṣe ní Presidential Villa ní Abuja ni wọn ti kede awon ẹbùn wọnyi.
Ọjọ Sonde ni Super Falcons lu iko agbaboolu Obinrin orilẹ ede Morocco pelu ami ayo meta si meji, ti won si gba ife ẹyẹ ohun, fun igbakewaa otooto.
Ààrẹ gbe oriyìn fun ẹgbẹ́ agbaboolu náà fún iṣẹ́ àṣeyọrí ti wọn se ni Morocco. Ó tẹnu mọ́ àṣeyọrí wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìgboyà, ìpinnu, àti àṣeyọrí, ó sì tẹnu mọ́ ọn pé àṣeyọrí wọn ju eré ìdárayá lásán lọ.
Aya ààrẹ, Sẹ́nátọ̀ Oluremi Tinubu, tún kí ẹgbẹ́ náà, ó sì ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn àwoṣe àti àpẹẹrẹ tó daa fún àwọn omodebirin orile-ede Naijira lati tele.
Alága Nigeria Governors’ Forum na tun kéde ẹ̀bùn afikún ti ₦10 million fún olúkúlùkù agbábọ́ọ̀lù àti àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórúkọ àwọn gómìnà 36 to ku.
Balogun Super Falcons, Rasheedat Ajibade, dupe gidi fun ìmọrírì ato ìtìlẹ́yìn ti ijoba ati awon omo Naijiria se fun won.
Ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì àkọ́lé WAFCON elekewaa ti wọn gba, ó sì pè fún àtìlẹ́yìn tó gbooro fun ere ìdárayá bọ́ọ̀lù awọn obìnrin láti gbé ipò Nàìjíríà sókè lágbàáyé nínú eré ìdárayá náà.







