Owó ti iye rẹ jẹ N1.39trillion ni Aare Bola Tinubu ti bu ọwọ lu fún àtúnṣe àwọn oju-ona káàkiri ipinlẹ Ìwọ̀-oòrùn gúúsù tó jẹ ti Yorùbá. Eleyii wà lára N787.14 billion ti ijọba àpapọ yà s’oto fún àtúnṣe àwọn oju-ọna káàkiri ipinlẹ mẹtala otooto lorileede yii.
Mínísítà fún iṣẹ ode, Dave Umahi lo fi ọrọ na to àwọn oníròyìn létí leyin ìpàdé awon apapọ t’awon to n se’joba ma a n ṣe, iyen Federal Executive Council Meeting lójó Mondee ọsẹ yìí.
Bakanna ni Ìjọba tun ya N205billion s’oto fún àtúnṣe awon ọnà to wa ni ilaoorun gúúsù (Southeast), N105 billion fun Iwoorun àríwá (Northwest) ati N30 billion fún ilaoorun àríwá (Northeast).
Umahi ṣàlàyé wípé orisirisi ise ode ati iṣẹ àwọn amayederun ni ijoba ya owó s’oto fun lato se káàkiri awon ìpínlẹ̀ mẹtala ohùn.
Bẹẹ náà ni Umahi tún sọ fun awọn akoroyin wipe ìjọba tun ti fi aye gba atunse ranpe lori awon eto sísọ oju-ọna di méjì (dualisation) to n lo lọwọ ní opopona Akure-Eta-Ogbese-Iju-Ekiti titi to fi dé opopona Ikere-Ado-Ekiti laarin ipinle Ondó ati Èkìtì