Ariwo ‘O ma se o’ l’awon èèyàn fi bo’nu léyìn ti won gbọ ìtàn ìrírí àgbà òṣèré tíátà kan to tún jẹ ẹni tó má n se ara losoo fun sinima yiya (make-up artist), Jumoke George l’asiko to t’enu b’oro nínú fonran ifọrọwọrọ kan to ṣe pẹlu òṣèré ẹgbẹ re, Abiola Adebayo.
George ni oju òun ti ri màbo àti wípé oju-titi ni kò jẹ k’oun o le sọrọ sita lórí nkan ti oju òun ri yii. O se àlàyé bi o se di eni to so soosi di ile gbígbé latari àìsàn kan to ko luu ati bi akọbi ọmọ ṣe di awati. Nínú ọrọ re, òṣèré tíátà na ni, odun mẹfa gbako l’oun o fi ni ibikan t’oun n gbe to je wipe opelope soosi lara oun.
O ni ni ibere odun yii ni aisan kan kolu oun to si se akoba fun ise oun ati opolopo nkan miran. Koda, pelu omije lójú ni Jumoke George fi n salaye ọrọ na lori fidio to ti se iforewero to si n tan káàkiri ori ayelujara.
O soro, ile kun: “Kii se gbogbo nkan na leeyan le ma a so kaakiri nitori itiju, sugbon nibi ti mo ba a de yii, mi o le dakẹ mo, o di dandan ki n soo sita fun aye gbo. Kii se wipe n o ri ise se, gbogbo igba ni awon eeyan ma n pe mi si enu ise, bo tilẹ je wípé o le je eekan laarin osu meta si merin, ko to di wipe mo bere si ni se aisan.
“Lati igba ti aisan na ti bere, mi o roju raaye lati lo se ise kankan, mi o le lo si oko sinima yiya mo nitori aisan na. Koda, lọdun to kọja yii, enikan ti e pe mi senu ise, ti o si san owo ise na fun mi, sugbon ko pe ni mo bere aisan, to je wipe ori aisan ohun ni mo na owo na si, ti mi o si le lo si oko ise ohun lati sise. Nígbà ti oro wa ri bee, nise mo kuku ya owo lati san an padà fun eni to pe mi s’enu ise.
“Nigba to se die, mo tun lo si oko sinima yiya miran sugbon mi o le se ise kankan nitori wipe gbigbe ni won gbe mi pada lo si ile nigba ti aisan yii tun ki mi mole. Latari wipe mo n wa iwosan kiri, orisirisi iwadi (test) ni mo ti se lati le mo hulehule nkan to n se mi gan an… koda, won ni ki n lo mu N400,000 wa fun test míràn ṣugbọn mi o ti e mo ibi ti mo ti ma ri owo ohun.” Bo se n s’oro na ni omijé n bo poroporo loju re.
Jumoke George tun te siwaju o, o ni odun mefa gbako l’oun fi n gbe inu soosi gegebi eni ti ko ni ile gbigbe, leyin ti won ti da eru oun sita latari wípé oun o lagbara lati ma a san owo ile to n fi gbogbo igba lo s’oke.
O ni, lásìkò yii ni soosi kan fun oun laaye kekere kan ninu soosi ohun lati ma a gbe sugbon itiju o je ki oun le soro sita, nitori wipe opolopo awon eeyan oun paapa o ti e mo wipe oun n la iru isoro bee koja lasiko na. O fi kun oro re wipe, aaye ti won fun oun o le gba gbogbo eru oun, idi niyen t’oun fi fi eru oun ha kaakiri pelu awon ore ati ojulumo. Koda, opolopo ninu awon eru t’oun fi aimoye odun ko jo lo si baje lasiko na.
“Ọdún kẹfà ree ti mo ti n gbe nínú soosi oun.” George salaye pelu omije loju re.
Lórí oro akọbi omo re to n wa kiiri, osere tiata na ni odo iya oun n’Ibadan ni Adeola n gbe, nibe na si ni won ti so fun oun wipe awon o kan deede ri Adeola mo. Sugbon nigba to to asiko kan, omo oun pe iya oun, o si pe oun pelu wipe, ki awon o foriji oun nítorí oun atawon ore re kan ni won jumo sa kuro lorile ede Naijiria lo si ilu ibikan latari wipe awon n wa bi aye awon yoo se daa. George ni, oun o mo ilu ohun, bee loun o si le so ni pato ibi ti ọmọ na wa lowolowo bayii.
Sugbon sa o, o ni owo okunrin kan toun tun bi toruko re nje Ife lo ti n dúró ti oun to n ran oun lowo. Koda, Ife paapaa ti je gbese lori oro oun, debi wipe o ya owo N2m lati se itoju oun ṣugbọn ti koi ti ri owo na san padà di bi a ti n soro yii
George wa rawo ebe si awon alaanu ènìyàn lati ran oun lọwọ, ati paapaa julo ki won a gba ádùrá fun oun